Abstract
Oríṣìíríṣìí ète ni àwọn jagunjagun máa ń ṣàmúlò láyé àtijọ́ láti fi ṣẹgun ̀ ọ̀ tá. Díẹ̀ lára àwọn ète wọ̀ nyí ni ìdẹ́ rùbani, olè jíjà, agbára oògùn àti bíba irè oko àwọn ọ̀ tá wọn jẹ́ . Àwọn iṣẹ́ ìwádìí ti wáyé lóríṣìíríṣìí lórí ogun jíjà láwùjọ Yorùbá ṣùgbọ́ n kò sí iṣẹ́ ìwádìí kan gbòógì tó ṣe àgbéyẹ̀ wò ewì gẹgẹ́ ́ bí ète ogun jíjà ní pàtó, ní kíkún. Lọ́ nà àti dí àlàfo yìí, iṣẹ́ ìwádìí yìí fi ojú ìmọ̀ - ìtàn-mọ́ -lítíréṣọ̀ ṣe àtẹgùn láti ṣe àgbéyẹ ̀ ̀ wò ewì gẹgẹ́ ́ bí ète ìjagun ní àwùjọ Yorùbá. A mọ̀ -ọ́ nmọ̀ ṣàṣàyàn àwọn ogun tí ó ti wáyé nínú ìtàn láwùjọ Yorùbá nínú èyí tí wọ́ n ti ṣàmúlò ewì láti ṣẹgun ni. A fi ọ ́ ̀ rọ̀ wá àwọn àgbà àti àwọn tó nímọ̀ nípa ogun lẹ́ nu wò. Bákan náà ni a ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ewì tí wọ́ n lò, lọ́ nà àti mọ ìdí tí ète náà fi mú ọ̀ tá tí wọ́ n dẹ ẹ́ fún. Orin lóríṣìíríṣìí àti oríkì ni iṣẹ́ ìwádìí ṣe àfihàn pé wọ́ n lò gẹgẹ́ ́ bí ète láti mú ọ̀ tá nínú ogun tí a yẹ̀ wò. Bákan náà ni ó hàn gbangba nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí pé ewì gẹgẹ́ ́ bí ète mú àwọn ọ̀ tá nítorí ọ̀ nà tí wọ́ n gbà lò ó fún ìdẹ́ rùbani, ìdájàsílẹ̀ , ìtannijẹ, ìránnilétí, ẹ̀bẹ̀ àti àyẹ́ sí. Ìgúnlẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí ni pé idà olójú méjì ni ewì jẹ́ . Bí a ṣe le lò ó gẹgẹ́ ́ bí ète ìdógunsílẹ̀ náà ni a lè lò ó láti pẹ̀rọ̀ ogun. Nítorí náà, ewì tí í ṣe ogún ìbí Yorùbá ni a le ṣàmúlò láti dènà tàbí pẹ̀tù sí aáwọ̀ kí ó tó di ogun lọ́ nà àti mú àlàáfíà àti ìdàgbàsókè bá àwùjọ.
This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.